Malachi 3:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ọjọ́ àwọn baba-ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò se padà?’