Mark 1:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n.