Mark 1:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapanámù, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsimi, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó sì ń kọ́ni.