Mark 1:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kẹ́kẹ́ bá pamọ́ gbogbo àwọn eniyan lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọn ń wí láàrin ara wọn pé, “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ titun ni! Pẹlu àṣẹ ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrin ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ titun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.”