Mark 1:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọkunrin náà jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọpọlọpọ eniyan, ó ń rán ọ̀rọ̀ náà mọ́ ẹnu, tóbẹ́ẹ̀ tí Jesu kò fi lè wọ inú ìlú ní gbangba mọ́, ṣugbọn ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí eniyan. Sibẹ àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ibi gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkì, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jésù kò sì le wọ ìlú ní gba-n-gba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní ihà. Ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.