Mark 1:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ilẹ Judea, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu jade tọ̀ ọ lọ, a si ti ọwọ́ rẹ̀ baptisi gbogbo wọn li odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.