Mark 10:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Jésù kúrò ní Kapanámù. Ó gba gúsù wá sí agbègbè Jùdíà, títí dé ìlà oòrùn odò Jọ́dánì. Bí i ti àtẹ̀yìnwá, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kọ́ wọn pẹ̀lú bí i ìṣe rẹ̀.