Mark 10:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ pe, awọn ti a nkà si olori awọn Keferi, a ma lò ipá lori wọn: ati awọn ẹni-nla wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìdí èyí, Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn.