Mark 11:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wá si Jerusalemu: Jesu si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si tari tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ti wọ́n padà sí Jerúsálémù, ó wọ inú tẹ́ḿpílì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpílì ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.