Mark 11:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun’ ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.