Mark 11:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì ẹni tí ó ṣẹ̀ yín. Baba yín lọ́run yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.”