Mark 11:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si tún wá si Jerusalemu: bi o si ti nrìn kiri ni tẹmpili, awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbàgba, tọ̀ ọ wá,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerúsálémù. Bí Jésù ti ń rìn kíri ni tẹ́ḿpílì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn tí ń kọ́ni ni òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.