Mark 12:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bẹ̀rẹ si ifi owe ba wọn sọ̀rọ pe, ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si ṣọgba yi i ká, o si wà ibi ifunti waini, o si kọ́ ile-isọ si i, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si àjo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ síí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan dá oko àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yì i ká, ó sì gbẹ́ ihò níbi tí omi yóò ti máa jáde fún ìtọ́jú ohun ọ̀gbìn. Níkẹyìn, ó gbé oko fún àwọn olùtọ́jú, ó sì lọ ìrìnàjò tí ó jìnnà.