Mark 12:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n fún un ní ọ̀kan. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ó wà ní ara rẹ̀ yìí?” Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Késárì ni.”