Mark 12:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jésù ti dáhùn dáadáa. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”