Mark 12:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikíni li ọjà,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ́ra lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́-òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígun rìn kiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọja,