Mark 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó rán ẹrú mìíràn lọ, pípa ni wọ́n pa á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọpọlọpọ àwọn ẹrú mìíràn, wọ́n lu àwọn kan, wọ́n pa àwọn mìíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tún rán omiran; eyini ni nwọn si pa: ati ọ̀pọ miran, nwọn lù miran, nwọn si pa miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmiran.