Mark 12:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn alágbàro náà wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ jẹ́ tiwa.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn oluṣọgba wọnni wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ogún rẹ̀ yio si jẹ tiwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọmọ baba olóko, wọ́n sọ fún ara wọn pé, ‘Ọmọ rẹ̀ ló ń bọ̀ yìí. Òun ni yóò jogún oko yìí tí baba rẹ̀ bá kú. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, lẹ́yìn náà oko náà yóò di tiwa.’