Mark 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá mú yín, tí ẹ sì dúró níwájú adájọ́, ẹ má ṣe dààmú nípa ohun tí ẹ ó wí fún ààbò. Ẹ ṣáà sọ ohun tí Ọlọ́run bá fi sí yín lọ́kàn. Ẹ̀yin kọ́ ní yóò sọ̀rọ̀, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.