Mark 13:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti joko lori òke Olifi ti o kọju si tẹmpili, Peteru ati Jakọbu, ati Johanu ati Anderu, bi i lẽre nikọ̀kọ wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé,