Mark 13:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin ko mọ̀ igba ti bãle ile mbọ̀wá, bi li alẹ ni, tabi larin ọganjọ, tabi li akukọ, tabi li owurọ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí sọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò da. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.