Mark 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.