Mark 13:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyè sára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú tẹ́ḿpìlì wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn gómìnà àti níwájú àwọn ọba pẹ̀lú, nítorí tí ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.