Mark 14:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn si ti joko ti nwọn njẹun, Jesu wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn, ani on na ti mba mi jẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jésù wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fí mí hàn.”