Mark 14:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Peteru tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Bí ó bá kan ọ̀ràn pé kí n bá ọ kú, sibẹ n kò ní sẹ́ ọ!” Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Pétérù faraya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́ rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.