Mark 14:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila dé, pẹlu àwọn eniyan tí ó mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lojukanna, bi o si ti nsọ lọwọ, Judasi de, ọkan ninu awọn mejila, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà, pẹlu ọgọ, lati ọdọ olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbagba wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Júdásì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ́ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbààgbà Júù ni ó rán wọn wa.