Mark 14:72 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹsẹkẹsẹ, àkùkọ kọ ní ẹẹkeji. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta!” Orí Peteru wú, ó bá bú sẹ́kún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lójú kan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Pétérù rántí ọ̀rọ̀ Jésù fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, ìwọ yóò ṣẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkùn.