Mark 15:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n ti fi ṣe ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì kúrò ní ara rẹ̀, wọ́n fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n bá fà á jáde láti lọ kàn án mọ́ agbelebu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elésè àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.