Mark 15:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí aṣọ rẹ̀ láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn báà lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.