Mark 15:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn obinrin kan wà ní òkèèrè tí wọn ń wo gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ninu wọn ni Maria Magidaleni wà, ati Maria ìyá Jakọbu kékeré ati ìyá Josẹfu, ati Salomi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn obinrin pẹlu si wà li òkere nwọn nwò: ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu kekere, ati ti Jose ati Salome;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń najú wò ó láti òkèèrè. Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin náà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù kékeré àti ti Jósè àti, Ṣálómè.