Mark 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lójúkan-náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé ẹní rẹ̀. Ó sì jáde lọ lojú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”