Mark 2:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn akọwe ati awọn Farisi si ri i ti o mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽtiri ti o fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti o si mba wọn mu?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn olùkọ òfin àti àwọn Farisí rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “È é ti rí tí ó fi ń bá àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”