Mark 2:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi a ma gbàwẹ: nwọn si wá, nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi fi ngbàwẹ, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “È é ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ kò gbààwẹ̀?”