Mark 2:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò kan ní Ọjọ́ Ìsinmi, bí Jesu ti ń la ààrin oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà jẹ bí wọn tí ń lọ lọ́nà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi Jesu ti nkọja lọ lãrin oko ọkà li ọjọ isimi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà bi nwọn ti nlọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe ni ọjọ ìsinmi, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrin oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọká.