Mark 4:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ní létí òkun Àwọn ijọ̀ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí òkun.