Mark 5:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wá sọdọ Jesu, nwọn si ri ẹniti o ti ni ẹmi èṣu, ti o si ni Legioni na, o joko, o si wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí-èṣù, tí ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ sì bọ̀ sípọ, ẹ̀rù sì bà wọ́n.