Mark 5:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà ati àwọn ẹlẹ́dẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ri fun ẹniti o li ẹmi èṣu, ati ti awọn ẹlẹdẹ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.