Mark 5:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n tún fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́. Ṣugbọn jíjá ni ó máa ń já ẹ̀wọ̀n, tí ó sì máa ń rún ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é. Kò sí ẹni tí ó lè fi agbára mú un kí ó fi ara balẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nigbapupọ li a ti nfi ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹ̀wọn de e, on a si dá ẹ̀wọn na meji, a si dá ṣẹkẹṣẹkẹ wẹ́wẹ: bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o li agbara lati se e rọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀.