Mark 5:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó bá lé gbogbo wọn jáde. Ó wá mú baba ati ìyá ọmọ náà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó wà pẹlu rẹ̀, ó wọ yàrá tí ọmọde náà wà lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi rẹrin ẹlẹya. Ṣugbọn nigbati o si tì gbogbo wọn jade, o mu baba ati iya ọmọ na, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, o si wọ̀ ibiti ọmọ na gbé dubulẹ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì fi í rẹ́rín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí.