Mark 6:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Nibikibi ti ẹnyin ba wọ̀ ile kan, nibẹ̀ ni ki ẹ mã gbé titi ẹnyin o fi jade kuro nibẹ̀ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe ṣípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà.