Mark 6:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Herodu ọba si gburo rẹ̀; (nitoriti okikí orukọ rẹ̀ kàn yiká:) o si wipe, Johanu Baptisti jinde kuro ninu oku, nitorina ni iṣẹ agbara ṣe nṣe lati ọwọ rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láìpẹ́, ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ nípa Jésù, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Jòhánù Onítẹ́bọ́mì jínde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ”