Mark 6:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níkẹ̀yìn Hẹ́rọ́díà rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, òun sì pèṣè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn jàǹkànjànkàn ní Gálílì.