Mark 6:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọmọ Hẹrọdiasi obinrin bá wọlé, ó bọ́ sí agbo, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó, inú Hẹrọdu ati ti àwọn tí ó wà níbi àsè náà dùn. Ọba sọ fún ọmọbinrin náà pé, “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́, n óo fi í fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọmọbinrin Herodia si wọle, ti o si njó, o mu inu Herodu dùn ati awọn ti o ba a joko, ọba si wi fun ọmọbinrin na pe, Bère ohunkohun ti iwọ fẹ lọwọ mi, emi o si fifun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Hẹ́rọ́díà wọlé tí ó jó. Inú Hẹ́rọ́dù àti àwọn àlèjò rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.”