Mark 6:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn aposteli Jesu pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe ati bí wọ́n ti kọ́ àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn aposteli si kó ara wọn jọ sọdọ Jesu, nwọn si ròhin ohungbogbo ti nwọn ti ṣe fun u, ati ohungbogbo ti nwọn ti kọni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àpósítélì ko ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni.