Mark 6:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Jésù ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.