Mark 6:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó rí i pé pẹlu ipá ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Ó tó bí agogo mẹta òru kí Jesu tó máa lọ sọ́dọ̀ wọn. Ó ń rìn lórí omi, ó fẹ́ kọjá lára wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ri nwọn nṣiṣẹ ni wiwà ọkọ̀; nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn: nigbati o si di ìwọn iṣọ kẹrin oru, o tọ̀ wọn wá, o nrìn lori okun, on si nfẹ ré wọn kọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó rí i wí pé àwọ́n ọmọ-ẹyin wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,