Mark 7:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bomi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bá, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)