Mark 7:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èése tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn àṣà wa àtijọ́ nítorí wọ́n jẹun láì kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ wọn.”