Mark 7:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé, ‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òótọ́ ni wòlíì Àìṣáyà ń sọ nígbà tí ó ń ṣe àpèjúwe yín, tó wí pé: “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.