Mark 8:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù mọ ohun tí wọ́n sọ láàrin ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èése ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú búrẹ́dì lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsí i sì títí di ìsinyìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni?